AYÒ OGÚNDERÉ The game of Chess in Yoruba

AYÒ OGÚNDERÉ
The game of Chess in Yoruba

Bí mo tí yo̩ sì yàrá náà ni mo rí àwo̩n ènìyàn mi tí wó̩n ń s̩eré orís̩irís̩i. Àwo̩n mìíràn ńdá àpárá wó̩n sì ńwo àwo̩n tí ńta ayò. Mo lo̩ tààrà sì ò̩do̩ Bínúpo̩ta bí ó ti jókòó lórí àga kan, mo sì jókòó sì iwájú rè̩. Àgádàte̩ kan wà láàárín àwa méjèèjì eléyìí tí ó ga ko̩já ikùn wa bí a tí jókòó. Ò̩gbé̩ni náà sì wa’wó̩ sì o̩mo̩ è̩hin rè̩ kan e̩ni tí ó gbé ayò Ogúnderé kan àti ò̩ti e̩lé̩rìndòdò méjì wá sì iwájú wa. Inú mi dùn púpò̩ láti ta ayò yí. E̩ jé̩ kí n s̩àlàyé nípa ayò náà.

Ogúnderé ni eré ayò kan tí wo̩n ma ńta lójú o̩pó̩n oníkàlákìní àwò̩ dúdú àti àwo̩ funfun. O̩mo̩ ayò mé̩rindínlógún ni ó wà ní ilé èkínní tí irú rè̩ sì wà ní ilé èkejì bákannáà. Àpapò̩ o̩mo̩ ayò náà sì jé̩ méjìleló̩gbò̩n. Ìs̩o̩wó̩ ta ayò yí dàbí ìgbà tí ikò̩ méjì bá wà ní ojú ogun tí wó̩n sì dojú ija ko̩ ara wo̩n. Ikò̩ ilé kìnníí ni àwo̩n ìlàrí-ogun mé̩jo̩ níwájú tí wo̩n tò ní fè̩gbé̩kè̩gbé̩. Àwo̩n wò̩nyí ni ìs̩é̩wé̩lé̩ ogun.

Àwo̩n àgbà ò̩jè̩ ogun mé̩jo̩ sì tò sí e̩hin wo̩n pè̩lú. bé̩è̩ gé̩lé̩ ni àwo̩n ikò̩ alátakò kejì náà rí àyàfi àwò̩ tiwo̩n tó dúdú s̩ùgbó̩n tí àwò̩ ilé kejì jé̩ funfun. Orí ilè̩ tí wo̩n ńrìn sì nì e̩yo̩ onígun-mé̩rin tí wo̩n jé̩ àmúlùmálà dúdú àti funfun. Gbogbo àmúlùmálà dúdú àti funfun tí o̩mo̩ ayò lè gbé e̩sè̩ sì lórí o̩pó̩n náà sì jé̩ mé̩rìnléló̩gó̩ta. Bí o̩mo̩ ayò ba ńgbé e̩sè̩ ní ò̩kò̩ò̩kan, yíò gbé e̩sè̩ mé̩jo̩ ní ìló̩po mé̩jo̩ láti lè kárí e̩yò̩ onígun-mé̩rin náà.

Lára àwo̩n àgbà ò̩jè̩ mé̩jo̩ tó wà lé̩hìn la tí rí O̩ba kan àti olórì rè̩ tí wó̩n wà ní àárín, olórì sì dúró lé̩gbè̩é̩ òsì o̩ba. Àwo̩n abo̩rè̩ méjì ló tún kan tí ò̩kan wà ni o̩wó̩ ò̩tún o̩ba pé̩kípé̩kí tí èkejì sì wà ní o̩wó̩ òsì olórì. L’é̩hìn èyí ló kan àwo̩n elés̩in méjì, ò̩kan wà lé̩gbè̩é̩ abo̩rè̩ o̩wó̩ ò̩tún o̩ba, èkejì sì wà lé̩gbè̩é̩ òsì abo̩rè̩ olórí. As̩áájú méjì ló tún wà nínú àwo̩n àgbà ò̩jè̩ ayò yí, ò̩kò̩ò̩kan sì kángun lapá ò̩tún àti lápá òsì. E̩ jé̩ kí n wá so̩ òfin e̩sè̩ gbígbé àti ayò pípa nínú eré ayò yí.

Àwo̩n ìlàrí ogun mé̩jo̩ tó wà níwájú yíò gbé e̩sè̩ ló̩kò̩ò̩kan síwájú níkan, wo̩n yíò sì pa o̩mo̩ ayò tó bá sún mó̩ wo̩n ní è̩pé̩lè̩be̩ o̩wó̩ ò̩tún tàbí o̩wó̩ òsì. S̩ùgbó̩n tí ayò ba kó̩kó̩ bè̩rè̩, wo̩n lè gbé e̩sè̩ méjì lé̩è̩kannáà. Ìgbe̩sè̩ yí dàbí ìgbà tí ènìyàn bá fé̩é̩ s̩ígun, lé̩hìn tí o̩ba àti àwo̩n ìjòyè rè̩ tí so̩ ò̩rò̩ kóríyá fún àwo̩n o̩mo̩ ogun.

Àwo̩n mìíràn wa tí ò̩rò̩ yi yíò wu wo̩n lórí jo̩jo̩ débi wípé wo̩n yíò sáré dìgbòlùjà láìbìkítà ewu kankan. Àwo̩n wò̩nyí ni ìlàrí ogun tí ó gbé e̩sè̩ lé̩è̩méjì àkànpò̩, wó̩n sì óò yìn’bo̩n sí apá ò̩tún àti àpa òsì s̩íwájú. Eléyìí mu kí ìrìn wó̩n lo̩ gbo̩rangandan s̩íwájú s̩ùgbó̩n wo̩n kò leè padà sé̩hìn mó̩ bí wó̩n bá ti gbé e̩sè̩ kan tàbí méjì àkànpò̩.

Ayò tí ó bá wà ní è̩pé̩lè̩be̩ síwájú ìlàrí níkan ni ìlàrí lè jé̩. Èyí tí ó bá kò ní pè̩kíǹrè̩kí, wo̩n yíò kan dínà fún ara wo̩n ni, wo̩n kò leè jé̩ ara wo̩n. Bí ayò kan bá sì jé̩ òmìíràn, ayò tí wo̩n je̩ náà yíò kúrò ní ojú o̩pó̩n bó̩ sí ìta, ayò tó sì jé̩é̩ yíò gba ibùdó rè̩. yàtò̩ sí àwo̩n òfin wò̩nyí tí ńtó̩ igbe̩sè̩ ìlàrí, òfin kan wà tí wo̩n kìí sábà lò nítorípé ó s̩òro láti tètè mò̩ó̩ lò nípa ìrìn àwo̩n ìlàrí wò̩nyí, eléyìí sì ni a lè pè ní “àpalo̩” nítorípé láàárín àwo̩n ò̩ta níkan ni wó̩n tí ńlo òfin yìí, e̩ jé̩ kí a s̩ì fi sílè̩ na.

As̩áájú ni o̩mo̩-ayò tí n ó tún so̩ ìrìn rè̩ lójú o̩pó̩n àti bí ènìyàn tí lè fi je̩ ayò mìíràn. Òun ló bè̩rè̩ ló sì kángun àwo̩n àgbà ò̩jè̩ lé̩gbè̩é̩ kinni àti lé̩gbè̩é̩ keji. Ò̩gbonrangandan ni ìrìn rè̩ yálà s̩íwájú tàbí sì è̩hìn, sé̩gbè̩é̩ ò̩tún tàbí sé̩gbè̩é̩ òsì, ó sì lè gbé iye e̩sè̩ tí ó wùú lé̩è̩kans̩os̩o bí ayò kan kò bá sí ní ojú òpó rè̩. Ìdí tí mo fi pe orúko̩ o̩mo̩-ayò yí ní As̩áájú ni wípé ó ndúró fún àwo̩n olórí-ogun oníkè̩ké̩.

Nínú òye ológun ilè̩e̩ wa, olóyè As̩áájú ló maa ns̩íwájú ogun, òun sì ni olórí àwo̩n e̩lé̩s̩in. Nínú ayò yí, As̩áájú ni o̩mo̩ ayò tó bè̩rè̩ tó sì parí ìlà tí àwo̩n àgbà ò̩jé̩ tò sì lé̩hìn. Bí kò ba sì e̩yo̩ ayò kankan láàárín o̩ba àti As̩áájú ní orí ìlà tí àwo̩n àgbà ò̩jè̩ ayò tò sí lé̩hìn, As̩áájú leè dá ààbò bo o̩ba nípa kíka e̩sè̩ méjì sìnú o̩pó̩n só̩dò̩ o̩ba tí o̩ba náà yíò sì fo orí rè̩ bó̩ sì kò̩rò̩ igun o̩pó̩n.

Eléyìí lè s̩eés̩e nígbà tí o̩ba kò ba tíi gbé e̩sè̩ kan ri láti ìgbà tí ayò tí bè̩rè̩. Ìsásíkò̩rò̩ yi ni a sì ńpè ní o̩bá-paramó̩, nítorípé bí o̩wó̩ bá ti te̩ o̩ba, ayò ti tán nìye̩n. Òrùlé wó̩go̩wò̩go̩ ni àmìn ìdánimò̩ ayò As̩áájú yí. Bí ènìyàn bá sì to ayò rè̩ dáadáa, As̩áájú ò̩tún yíò wà lójú ibi tó funfun tí t’òsì yíò sì wa lójú ibi tó dúdú.

E̩lé̩s̩in ló tún kan lé̩hìn As̩áájú, ìrìn rè̩ ló sì lójúpò̩ jù nínú àwo̩n àgbà ò̩jè̩ yí. A tún lè pe o̩mo̩ ayò náà ní Sàrùmí nítorípé nínú òye ogun Yorùbá, Sàrùmí jé̩ ò̩kan pàtàkì ìjòyè tíí gbórí e̩s̩in jagun. Bí ènìyàn kò bá mo̩ òfin tó rò̩ mó̩ ìrìn rè̩ lójú o̩pó̩n, ò̩gá ò̩ta lè fi e̩lé̩s̩in pa gbogbo o̩mo̩ ayò e̩nìkejì rè̩. S̩íkúns̩íkún ni yíò sì máa mú wo̩n ní ò̩kò̩ò̩kan.

Bí e̩lé̩s̩in yíò bá rìn, e̩sè̩ mé̩ta ni yíò gbé, yíò bé̩ gijagija s̩íwájú lé̩è̩méjì, yíò sì ba búrú sí apá kan níwájú tàbí apá kejì. Bí ó bá sì jé̩ è̩gbé̩ náà ni, yíò gbé e̩sè̩ méjì sì è̩gbé̩ yíò sì ba sì apá kan tàbí apá kejì. Ìtumò̩ èyí ni pé, e̩sè̩ mé̩ta ni e̩lé̩s̩in yíò gbé lé̩è̩kans̩os̩o, méjì àkókò síwá, sé̩hìn tàbí sì è̩gbé̩; eyo̩ kan tó kù ni yíò sì fi ba sì apá kan tàbí èkejì. Nítorínáà, ìrìn e̩lé̩s̩in dàbí àmì ˥, ˩, ibi tí ó bá ba sí náà ló sì jé̩ sí. Orí e̩s̩in ni ènìyàn yíò fi da o̩mo̩ ayò yí mò̩.

Abo̩rè̩ ló tun kàn, àwo̩n ló sì súnmó̩ o̩ba àti olórì pé̩kípé̩kí. È̩pé̩lè̩be̩ tàbí ìbúm̀bú ni wo̩n máa ńrìn. Ìye̩n ni pé, òpó ìrìn wo̩n daago sé̩gbè̩é̩ ò̩tún tàbí òsì, gbogbo ayò ilé kejì tí ó bá wà ní ojú òpó tó daago yìí ni wó̩n lè je̩. Kò sì iye e̩sè̩ tí àwo̩n náà kò leè gbe lé̩è̩kans̩os̩o. Bí ènìyàn bá sì to ayò rè̩ dáadáa, Abo̩rè̩ ò̩tún yíò wa lójú ibi to funfun, tí òsì yíò sì wa lójú ibi to dúdú.

O̩ba wa ni o̩wó̩ ò̩tún olórì. Olórì ló lagbára jù nínú àwo̩n ìjòyè yí nítorípé kò sí bí òun kò tí lè rìn àyàfi wípé kò leè rìn bíi ti e̩lé̩s̩in. Olórì leè fò fè̩rè̩ lo̩ ní ò̩gbo̩nrangandan, ó lè rìn ní ìbú, ó sì leè rìn ní è̩pé̩lè̩be̩. Ó lè gbé e̩sè̩ kan, ó sì lè gbé iye e̩sè̩ mìíràn tí ó wùú.

Bóyá ni kìí s̩e wípé àwo̩n tí ó s̩e ayò yí ńfé̩ s̩e àfihàn Ayaba tó wà ní wúndíá s̩ùgbó̩n tí ó gbójúgbóyà ni. O̩ba kò leè gbé ju e̩sè̩ kan s̩os̩o lé̩è̩kan lo̩. Ó lè rìn síwá, sé̩hìn , ó sì le rìn sí è̩gbé̩ àti sí ìgún.* Ó jo̩ bí e̩ni wípé árúgbó ni o̩ba yìí nítorípé e̩sè̩ kò̩ò̩kan ni ó lè gbé bí árúgbó onìrìn jè̩lé̩ńké̩. Bí àwo̩n ò̩tá bá sì ti ká o̩ba mó̩ débi wípé kò sí ò̩nà tí yíò gbà, ojú òpó èyíkéyìí ota rè̩ ni yíò gbe e̩sè̩ le, ayò tan niyen, ilé keji to fún o̩ba náà pa ló na ayò ohun niyen.

Nítorínáà, gbogbo ìgbà tí o̩ba ba tí wa ni ojú òpó ìjé̩-ayò ilékeji ni e̩ni tí o ta tan yíò pariwo fún e̩ni tí o kan láti ta wípé, “O̩bá wo̩ gàù!” tàbí ní àkékúrú “Gàù!” Onítò̩hún sì tètè gbo̩dò̩ wá ò̩nà bí o̩ba rè̩ yíò s̩e fi ara pamó̩ kúrò fún àwo̩n ayò ilé kejì rè̩.

O̩gbó̩n orís̩irís̩i ni ènìyàn lè dá láti s̩e èyí; onítò̩hún lè gbé ayò rè̩ mìíràn tí kò níláárí bí ìlàrí kan s̩ùgbó̩n tí ó wà ní ìtòsí sì iwájú o̩ba láti dáàbò bo o̩ba. Ó sì tún lè gbé o̩ba sí kò̩rò̩ kan lé̩yìn ayò re̩, s̩ùgbó̩n o̩ba náà kò gbo̩dò̩ gbé ju e̩sè̩ kan s̩os̩o lé̩è̩kan lo̩. Bí wo̩n ba sì tí jé̩ ayò e̩nìkan tán ku o̩ba níkan, onítò̩hún yíò ma gbé o̩ba rè̩ sá le̩sè̩ kò̩ò̩kan títí alátakò rè̩ yíò fi fún o̩ba náà pa tí kò ní lè gbé e̩sè̩ ko̩kan mó̩. Nígbàyí ni e̩ni tí ó jáwé olúborí yíò so̩ wípé “Mo há o̩ba pa” tí e̩ni tí o fìdí re̩mi náà yíò sì gba wípé wó̩n ti na òun.

Bí èmi àti Bínúpo̩ta tí ńta ayò yí ni àwo̩n ènìyàn tí ńgbé àga súnmó̩ wa tí wó̩n sì ńdá àpárá orís̩irís̩i. E̩ni tí ara rè̩ kò bá gba àwàdà kò leè tayò. Ńs̩e ni mo ńfi gbogbo àwàdà tí wo̩n ńfi mí s̩e ré̩rìn-ín ní tèmi. Lóòótó̩, Bínúpo̩ta mo̩ ayò náà ta púpò̩, s̩ùgbó̩n mo tí pinu wípé kàkà kí eku má jé̩ sèsé, yíò fi s̩e àwàdanù ni.

L’é̩hìn tí ó tí pa ìlàrí ayò mi bíi márùn-ún tí èmi kò sì pa ju ìlàrí o̩mo̩ ayò rè̩ méjì lo̩, àwo̩n ènìyàn bè̩rè̩ síí wòó wípé yíò nà mí láyò náà. Mo múra tìí, mo sì ńfi sùúrù wo gbogbo ò̩nà tí àwo̩n ayò rè̩ lè gbà pa ayò mi kí ntóó ta. Mo tún ńs̩e àfojúsùn nínú mi, àwo̩n ò̩nà àrekérekè tí Bínúpo̩ta ngbèrò láti ló láti fi pa ayò mi. Eléyìí sì jé̩ kí n máa pé̩ díè̩ láti ta ayò.

Ayò ogúnderé kúrò ní kèrémí. Bí ènìyàn kò bá jé̩ aláròjinlè̩ tí o leè wòye s̩e àforírò ohun tí e̩le̩gbé̩e̩ rè̩ yíò ta kò lè ta ayò yí. Lé̩è̩kannáà ni mo ríi wípé Bínúpo̩ta tí gbagbera, ayò abo̩rè̩ rè̩ kan ni o̩wó̩ mi kó̩kó̩ tè̩, ó pariwo lóhùn rara wípé òun gbe! Inú mi sì dùn wípé o̩wó̩̩ò̩ mi ba Bínúpo̩ta lónìí.

Ayò náà dùn nítorípé ò̩kan nínú àwo̩n olóyè ayò rè̩ ni. Òun ló sì máa ńrìn ni è̩pé̩lè̩be̩ bí ìfò alápàáǹdè̩dè̩. S̩ùgbó̩n o̩kàn mi ńso̩ lápákan wípé ó fi ayò èyí tàn mí sí iwájú ni. Bí a tí ńta ayò náà lo̩ ni e̩lé̩s̩in rè̩ ńfò gìjà-gìjà síhìn-in só̩hùn-ún. Ìrìn ayò náà sì sòro láti mò̩ nítorípé ó lè fo orí ayò mìíràn ko̩já. Nígbà tí ó s̩e, ò̩kò̩ò̩kanni Bínúpo̩ta ńfi e̩lé̩s̩in rè̩ mú ayò mi, bí mo sì s̩e gbìyànjú tó ó na ayò náà lé̩è̩méjì kí ntó na ò̩kan péré. L’é̩hìn èyí ó nà mí ní márùn-ún láìlábùlà.

Mo dìde kúrò lórí ijókòó, e̩lòmíràn sì bó̩ sí ibè̩. Bínúpo̩ta sì tún fún onítò̩hún ní márùn-ún sí méjì. Níbí sìni gbogbo wa ti túká tí a padà sí orí ibùsùn wa nítorí pé ara wa s̩ì ńròó wípé orí ilé Ayé ni òun wà.

Note:
The chess pieces are:
Ìṣẹ́wẹ́lẹ́ – Pawn
Aṣááju – Rook
Ẹlẹ́ṣin, Sàrùmí – Knight
Abọrẹ̀ – Bishop
Olorì – Queen
Ọba – King

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top